Yíńká Òdùmákín – Erin wó!
Erin wó
Erin wó
Erin wó
Erin wó ní gbó!
Àjànàkú sùn bí òkè
Gbogbo ọ̀gàn pa rọ́rọ́!!
Erin wó
Ọláyíńká, ọmọ Òdùmákín lọ!!!
Erin mà wó o
Yíńká Òdùmákín, erin wó!
Ọláyíńká Òdùmákín, erin wó
Ọláyíńká, ọmọ Òdùmákín, erin wó!!
Erin wó ní gbó, erin lọ
Gbogbo igbó pa dẹ́dẹ́ dẹ́dẹ́dẹ́
Ó lọ, ó ṣe bẹ́ẹ̀, ó lọ ní wẹ́rẹ́!!!
Akíkanjú, Ajagun, ọmọ Yorùbá bá ogun Coronavirus lọ!
Ajakalẹ ààrùn Coronavirus burúkú tí ó bẹ sílẹ̀
láti lorilẹ-ede China, lọ́dún tó kọjá,
ló bá mú akíkanjú ológun ọmọ Yorùbá Nàìjíríà lọ ní 2021!!!
Ọmọ Òdùmákín, akọni to ṣubu loju ija lasiko ajakalẹ arun COVID-19, o di gbé re ooo
Ọláyíńká, o di olóògbé, ni 2021, erin mà wó o!!!
A já takuntakun, takuntakun lọ
Ọláyíńká, akíkanjú ọmọkùnrin ọmọ Oòduà
Ọmọ jẹ́jẹ́, àbíjà kunkun!!!
A gbìjàfóníjà, abóníjàjàá, abóníjà làá lọ
Ọláyíńká, akíkanjú olùṣọ̀rọ̀ ọmọ Oòduà
Ọmọ jẹ́jẹ́, àbíjà kun kun kun!!!
Ó lọ, o lọ, o lọ
Ẹni ire lọ
Ọláyíńká lọ!
Aya rẹ rere, Joe Okei-Odumakin ń ṣe àárò rẹ o
Awon ọmọ rẹ n ṣe àárò rẹ o
Gbogbo ọmọ Yorùbá jákèjádò àgbáyé ń kàárò rẹ o!!
Gbogbo ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ń dárò rẹ o
Gbogbo ọmọ Afrika ń dárò rẹ o
Gbogbo àgbáyé ń kàárò rẹ o!!!
Ó di gbére
Ó dà rìn nàkò
Ó dojú àlá o
Ọláyíńká ògidi ọmọ ká arò óò jí re
Ọláyíńká akíkanjú, ọmọ Òdùmákín!!!
@ Funmilayo Adesanya-Davies
Saturday 3rd. April, 2021.
Signed
Princess Funmilayo Adesanya-Davies